3 àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni:Hánókù àti Pálù, Hésirónì àti Kárímì.
4 Àwọn ọmọ Jóẹ́lì:Ṣémáíà ọmọ Rẹ̀, Gógù ọmọ Rẹ̀,Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀.
5 Míkà ọmọ Rẹ̀,Réáíà ọmọ Rẹ̀, Báálì ọmọ Rẹ̀.
6 Béérà ọmọ Rẹ̀, tí Tígílátì-pílínésérì ọba Ásíríà kó ní ìgbékùn lọ: ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni òun jẹ́.
7 Àti àwọn arákùnrin Rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:Jélíélì àti Ṣékáríà ni olórí.
8 Àti Bélà ọmọ Ásásì ọmọ Ṣémà, ọmọ Jóẹ́lì tí ń gbé Áróérì àní títí dé Nébò àti Baaliméónì.
9 Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àti wọ ihà láti odo Yúfúrátè; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ si i ní ilẹ̀ Gílíádì.