46 Ọmọ Ámíṣì ọmọ Bánì,ọmọ Ṣémérì,
47 Ọmọ Máhílì,ọmọ Múṣì, ọmọ Mérárì,ọmọ Léfì.
48 Àwọn Léfì ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yókù ti Àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.
49 Ṣùgbọ́n Árónì àti àwọn ìran ọmọ Rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ọrẹ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a se ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti paláṣẹ.
50 Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Árónì:Élíásérì ọmọ Rẹ̀. Fínéhásì ọmọ Rẹ̀,Ábísúà ọmọ Rẹ̀,
51 Búkì ọmọ Rẹ̀,Húṣì ọmọ Rẹ̀. Ṣéráhíà ọmọ Rẹ̀,
52 Méráíótì ọmọ Rẹ̀, Ámáríyà ọmọ Rẹ̀,Áhítúbì ọmọ Rẹ̀,