50 Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Árónì:Élíásérì ọmọ Rẹ̀. Fínéhásì ọmọ Rẹ̀,Ábísúà ọmọ Rẹ̀,
51 Búkì ọmọ Rẹ̀,Húṣì ọmọ Rẹ̀. Ṣéráhíà ọmọ Rẹ̀,
52 Méráíótì ọmọ Rẹ̀, Ámáríyà ọmọ Rẹ̀,Áhítúbì ọmọ Rẹ̀,
53 Ṣádókù ọmọ Rẹ̀àti Áhímásì ọmọ Rẹ̀.
54 Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbégbé wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Árónì lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kóhátítè, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ ti wọn):
55 A fún wọn ní Hébírónì ní Júdà pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.
56 Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún kelẹ́bù ọmọ Jéfúnénì.