6 Àwọn ọmọ mẹ́ta Bẹ́ńjámínì:Bélà, Békérì àti Jédíáélì.
7 Àwọn ọmọ Bélà:Éṣíbónì, Húṣì, Ísíélì, Jérómótì àti Írì, àwọn máràrùnún. Awọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbàámọ́kànlá-ó-lé-mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn (22,034)
8 Àwọn ọmọ Békérì:Ṣémíráhì, Jóáṣì, Élíásérì, Élíóénáì, omírì, Jeremótù Ábíjà, Ánátótì àti Álémétì Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Békérì
9 Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún-ní ọ̀nà ogún-ó-lé nígba (20,200) Ọkùnrin alágbára
10 Ọmọ Jédíáélì:Bílíhánì.Àwọn ọmọ Bílíhánì:Jéúṣì Bẹ́ńjámínì, Éhúdì, Kénánà Ṣétanì, Tárí-Ṣíṣì àti Áhísáhárì.
11 Gbogbo àwọn ọmọ Jédíádì jẹ́ olórí ìdátan Àwọn ẹgbẹ̀rúnmẹ́tadínlógún-ó-lé-nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetan láti jáde lọ sí ogun.
12 Àwọn ará Ṣúpímè àti Húpímù jẹ́ àwọn atẹ̀lé fún Írì, àwọn ìran ọmọ Áhérì.