2 Nóhà ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Ráfà ẹ̀ẹ̀karùnún.
3 Àwọn ọmọ Bélà jẹ́:Ádárì, Gérà, Ábíhúdì,
4 Ábísúà, Námánì, Áhóà,
5 Gérà, Ṣéfúfánì àti Húrámù.
6 Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Éhúdì, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Gébà tí a sì lé kúrò lọ sí Mánáhátì:
7 Námánì Áhíjà àti Gérà, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Úṣà àti Áhíhúdù.
8 A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣáháráímù ní Móábù lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó Rẹ̀ sílẹ̀, Húṣímù àti Báárà.