29 Jélíélì, baba a Gíbíónì ń gbé ní Gíbíónì.Ìyáwó o Rẹ̀ a má jẹ́ Mákà,
30 Àkọ́bí Rẹ̀ a sì má a jẹ́ Ábídónì wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Ṣúrì, Kíṣì, Báláhì, Nérì, Nádábù,
31 Gédórì Áhíò, Ṣékérì
32 Pẹ̀lú Míkílótì, tí ó jẹ́ bàbá Ṣíméà. Wọ́n ń gbé lébá ìbátan wọn ní Jérúsálẹ́mù.
33 Mérì jẹ́ baba Kíṣì, Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù àti Ṣọ́ọ̀lù baba Jónátanì, Málìkíṣúà, Ábínádábù àti Ésíbálì.
34 Ọmọ Jónátanì:Méríbáì tí ó jẹ́ baba Míkà.
35 Àwọn ọmọ Míkà:Pítónì, Mélékì, Táréà, àti Áhásì.