33 Mérì jẹ́ baba Kíṣì, Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù àti Ṣọ́ọ̀lù baba Jónátanì, Málìkíṣúà, Ábínádábù àti Ésíbálì.
34 Ọmọ Jónátanì:Méríbáì tí ó jẹ́ baba Míkà.
35 Àwọn ọmọ Míkà:Pítónì, Mélékì, Táréà, àti Áhásì.
36 Áhásì jẹ́ bàbá a Jéhóádá, Jéhóádá jẹ́ baba a Álémétì Áṣíméfétì àti Ṣímírì, Ṣímírì sì jẹ́ baba a Móṣà.
37 Móṣà jẹ́ baba a Bínéà; Ráfà sì jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Éléásà ọmọ Rẹ̀ àti Áṣélì ọmọ Rẹ̀.
38 Áṣélì ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:Áṣíríkámù, Bókérù, Íṣímáélì, Ṣéáríà, Ọbádáyà àti Hánánì. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Áṣélì.
39 Àwọn ọmọ arákùnrin Rẹ̀ Éṣékì:Úlámù àkọ́bí Rẹ̀, Jéúṣì ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Élífélétì ẹ̀ẹ̀kẹ́ta.