15 Bákíbákárì, Héréṣì, Gálálì àti Mátaníyà, ọmọ Míkà, ọmọ Ṣíkírì, ọmọ Ásáfù;
16 Ọbadíà ọmọ Ṣémáíà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúnì; àti Bérékíà ọmọ Ásà, ọmọ Élíkánà, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Nétófá.
17 Àwọn Olùtọ́jú Ẹnu Ọ̀nà:Ṣálúmù, Ákúbù, Tálímónì, Áhímánì àti arákùnrin wọn, Ṣálúmì olóyè wọn,
18 ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Léfì.
19 Ṣálúmì ọmọ kórè ọmọ Ébíásáfì, ọmọ kórà, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ẹlẹ́gbẹ́ Rẹ̀. Láti ìdílé Rẹ̀ (àwọn ará kórà) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìlóró ẹnu ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ à bá wọlé ibùgbé Olúwa.
20 Ní ìgbà àkọ́kọ́ fíníhásì ọmọ Élíásérì jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú Rẹ̀.
21 Ṣékáríà, ọmọ Méṣélémíà jẹ́ Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní à bá wọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.