2 Nísìnsìn yìí, àwọn tí ó kọ́ kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ará Léfì àti àwọn Ìránsẹ́ ilé Olúwa.
3 Àwọn tí ó wá láti Júdà láti Bẹ́ńjámínì àti láti Éfíráímù àti Mánásè tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́:
4 Hútayì ọmọ Ámíhúdì, ọmọ Ómírì, Ọmọ Ímírì, ọmọ Bánì, ìran ọmọ Fárésì ọmọ Júdà.
5 Tí ará Ṣílò:Ásáíà àkọ́bí àti àwọn ọmọ Rẹ̀.
6 Níti ará Ṣérà:JégúélìÀwọn ènìyàn láti júdà sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).
7 Níti ará:Ṣálù ọmọ Mésúlámì, ọmọ Hódáfíà; ọmọ Hásénúà;
8 Íbínéíà ọmọ Jéróhámù; Élà ọmọ Húṣì, ọmọ Míkírì àti Mésúlámù ọmọ Ṣéfátíyà; ọmọ Régúélì, ọmọ Íbíníjà.