1 Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ipò Réhóbóámù gẹ́gẹ́ bí ọba lélẹ̀, tí ó sì ti di alágbára, òun àti gbogbo Ísírẹ́lì, pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n pa òfin Olúwa tì.
2 Nítorí tí wọn kò ṣọ̀ọ́tọ́ sí Olúwa. Ṣíṣákì ọba Ị́jíbítì dojúkọ Jérúsálẹ́mù ní ọdún karùnún ti ọba Réhóbóamù
3 Pẹ̀lú ẹgbẹ̀fà kẹ̀kẹ́ (12, 000) àti ọkẹ́ mẹ́ta àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Líbíyánì, Ṣúkísè àti Kúṣì, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Éjíbítì.
4 Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Júdà, pẹ̀lú wá sí Jérúsálẹ́mù bí ó ti jìnnà tó.
5 Nígbà naà, wòlíì Ṣémáíà wá sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Júdà tí wọ́n ti péjọ ní Jérúsálẹ́mù nítorí ìbẹ̀rù Ṣíṣáki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣíṣákì.”