2 Kíróníkà 12:8-14 BMY

8 Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàárin sísìn mí àti sísin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn.”

9 Nígbà tí Ṣíṣákì ọba Éjíbítì dojúkọ Jérúsálẹ́mù, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìsúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Sólómónì dá.

10 Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Réhóbóámù dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùsọ́ tí ó wà ní ẹnu isẹ́ ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́.

11 Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé Olúwa, àwọn olùsọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn apáta naà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́.

12 Nítori ti Réhóbóámù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú Olúwa yí padà kúrò lórí rẹ̀, a kò sì paárun pátapáta. Nítòótọ́, ire díẹ̀ wà ní Júdà.

13 Ọba Réhóbóámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi ní Jérúsálẹ́mù, ó sì tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Jérúsálẹ́mù, ìlú ńlá tí Olúwa ti yàn jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní èyí tí ó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ sí.

14 O sì ṣe búburú, nítorí tí kò múra ọkàn rẹ̀ láti wá Olúwa.