1 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jéróbóámù, Ábíjà di ọba Júdà.
2 Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mákà, ọmọbìnrin Úríélì ti Gíbéà.Ogun wà láàárin Ábíjà àti Jéróbóámù.
3 Ábíjà lọ sí ojú ogun pẹ̀lu àwọn ọmọ ogun ogún ọ̀kẹ́ (40,000) ọkùnrin alágbára, Jéróbóámù sì fa ìlà ogun sí i pẹ̀lu ogójì ọ̀kẹ́ (8,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára.
4 Ábíjà dúró lórí òkè Ṣémáráímù ní òkè orílẹ̀ èdè Éfiráímù, ó sì wí pé, Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ mi!
5 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run fún Dáfídì àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?
6 Síbẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, oníṣẹ́ Sólómónì ọmọ Dáfídì, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀.
7 Àwọn ènìyàn lásán aláìwúlò péjọ yí i ká, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Réhóbóámù ọmọ Sólomónì ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fún ra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.