4 Ábíjà dúró lórí òkè Ṣémáráímù ní òkè orílẹ̀ èdè Éfiráímù, ó sì wí pé, Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ mi!
5 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run fún Dáfídì àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?
6 Síbẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, oníṣẹ́ Sólómónì ọmọ Dáfídì, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀.
7 Àwọn ènìyàn lásán aláìwúlò péjọ yí i ká, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Réhóbóámù ọmọ Sólomónì ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fún ra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.
8 “Nísinsìn yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dáfídì. Ìwọ jẹ́ ọmọ ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lu rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jéróbóámù dà láti se Ọlọ́run yín.
9 Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Ọlọ́run jáde, àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ará Léfì. Tí ó sì se àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà èyí tí kì í ṣe àwọn Ọlọ́run.
10 “Ní ti àwa, Olúwa ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfaà tí ó ń sin Olúwa jẹ́ àwọn ọmọ Árónì àwọn ará Léfì sì n ràn wọ́n lọ́wọ́.