1 Ábíjà sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dáfídì. Ásà ọmọ rẹ̀ rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, orílẹ̀ èdè wà ní àlàáfíà fún ọdun mẹ́wàá.
2 Ásà ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́ ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
3 Ó gbé àwọn pẹpẹ àjèjì kúrò àti àwọn ibi gíga. Ó fọ́ àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀, ó sì gé àwọn òpó Áṣérà bolẹ̀.
4 Ó pa á láṣẹ fún Júdà láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wọn àti láti tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ àti àṣẹ.
5 Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Júdà. Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀.
6 Ó mọ àwọn ìlu ààbò ti Júdà, níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti wà ní àlàáfíà. Kò sí ẹnikẹ́ni ti o jagun pẹ̀lu rẹ̀ nígbà àwọn ọdun wọ̀n yẹn. Nítorí Olúwa fún un ní ìsinmi.