12 Olúwa lu àwọn ará Kúsì bolẹ̀ níwájú Ásà àti Júdà. Àwọn ará Kúsà sá lọ.
13 Ásà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé wọn ní jìnnà réré sí Gérárì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, àwọn ará Kúṣì ṣubú, wọn kò sì le sán padà mọ́. A fún wọn pa níwájú Olúwa àti ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọkùnrin Júdà kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógún.
14 Wọ́n pa gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní ẹ̀bá Gérárì, nítorí tí ìpayà Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ sórí wọn. Wọ́n kó gbogbo ìkógún àwọn ìletò yìí lọ, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀pọ̀ ìkógun ti wà níbẹ̀.
15 Wọ́n kọ lu àwọn ibùdó àwọn darandaran, wọ́n sì gbé àwọn ọ̀wọ́-ẹran àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ àti àwọn ìbákasẹ. Nígbà náà wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù.