7 “Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí” Ó wí fún Júdà, “Kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ile ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti bèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere.
8 Ásà ní àwọn ọmọ ogun ti ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin láti Júdà. Pẹ̀lú àwọn ohun èlò àwọn àpáta ńlá àti ọ̀kọ̀ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) láti Béńjamẹ́nì wọ́n dira pẹ̀lú àwọn apata kékèké àti àwọn ọrun. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ògbójú jagunjagun ọkùnrin.
9 Ṣérà ará Kúṣì yàn láti dojú kọ wọ́n, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ ogun pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kẹ̀kẹ́, wọ́n sì wá láti jìnnà réré bí Máréṣà.
10 Ásà jáde lọ lati lọ bá a. Wọ́n sì mú ibi ogun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣéfátanì lẹ́bá Máréṣà.
11 Nígbà náà, Ásà ké pe Olúwa Ọlọ́run baba a rẹ̀, ó sì wí pé “Olúwa kò sí ẹnìkan bí ì rẹ láti rán aláìlágbára lọ́wọ́láti dójú kọ ẹni ńlá. Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa gbẹ́kẹ̀ lé ọ àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi wá láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun yìí. Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run wa; má se jẹ́ kí ènìyàn kó ṣẹ́gun rẹ.”
12 Olúwa lu àwọn ará Kúsì bolẹ̀ níwájú Ásà àti Júdà. Àwọn ará Kúsà sá lọ.
13 Ásà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé wọn ní jìnnà réré sí Gérárì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, àwọn ará Kúṣì ṣubú, wọn kò sì le sán padà mọ́. A fún wọn pa níwájú Olúwa àti ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọkùnrin Júdà kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógún.