3 Olúwa sì wà pẹ̀lú Jéhóṣáfátì nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dáfídì ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Báálímù.
4 Sùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lẹ́ àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Ísírẹ́lì.
5 Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Júdà sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehóṣáfátì, Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọpọ̀.
6 Ọkàn rẹ̀ sì gbé sokè si ọ̀nà Olúwa, pẹ̀lúpẹ̀lù, ó sì mú ibi gíga wọn àti òrìṣà kúrò ní Júdà.
7 Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ Bẹni-Háílì, Obádíà Sekaríà, Nètaníélì Míkíà láti máa kọ́ ni nínú ìlú Júdà.
8 Wọ́n sì ní díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì, àní Ṣémáyà, Netaníà, Sebadíà, Ásáélì, Ṣémírámótì, Jéónátanì, Àdóníjà, Tóbíyà àti Tobi-Àdóníjà àti àwọn àlùfáà Élíṣámà àti Jéhórámù.
9 Wọ́n ń kọ́ ni ní agbégbé Júdà, wọ́n mú ìwé òfin Olúwa dání, wọ́n sì rìn yíká gbogbo àwọn ìlú Júdà wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.