2 Kíróníkà 18:3-9 BMY

3 Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jèhóṣáfátì, ọba Júdà pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Rámótì Gílíádì?”Jehóṣáfátì sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ ninú ogun naà”

4 Ṣùgbọ́n Jehóṣáfátì náà sì tún wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”

5 Bẹ́ẹ̀ ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì papọ̀, irínwó (4,000) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Rámótì Gélíádì tàbi kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?”“Lọ,” wọ́n dáhùn, “nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

6 Ṣùgbọ́n Jehósáfátì béèrè pé, “Ṣé kò ha sí wòlíì Olúwa níbí ẹni tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

7 Ọba Ìsírélì dá Jehóṣáfatì lóhùn pé, “Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ì bá tún béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorì kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Míkáyà ọmọ Ímílà.”“Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀,” Jehóṣáfátì sì dá lóhùn.

8 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, “Ẹmú Míkáyà ọmọ Ímílà kí ó yára wá.”

9 Wọ́n wọ aṣọ Ìgúnwà wọn, ọba Ísírẹ́lì àti Jehóṣáfátì ọba Júdà wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu bodè Samaríà, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.