2 Kíróníkà 19:4-10 BMY

4 Jéhóṣáfátì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ó sì jáde lọ padà láàárin àwọn ènìyàn láti Béríṣébà dé òkè ìlú Éfúráímù, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn.

5 Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi, Júdà.

6 Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsí ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́.

7 Nísinsin yìí jẹ́kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí orí rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

8 Ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, Jéhóṣáfatì yan díẹ̀ lára àwọn Léfì, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Ísírẹ́lì si pípa òfin Olúwa mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́. Wọn sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

9 Ó sì kìlọ̀ fún wọn wí pé. “Ìwọ gbọdọ̀ sìn pẹ̀lú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn pípé ní ìbẹ̀rù Olúwa.

10 Ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wà níwájú rẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé ìlú wọn bóyá ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn tàbí ìyókù òfin pẹ̀lú, paálásẹ ìlànà àti ẹ̀tọ́, ìwọ gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe dẹ́sẹ̀ sí Olúwa bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú yóò sì wá sórí yín, àti sórí àwọn arákùnrin. Ṣe èyi, ìwọ kò sì ní dẹ́ṣẹ̀.