5 “Ilé Olúwa tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn Ọlọ́run mìíràn lọ.
6 Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò ti le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún Olúwa, àyàfi ibi kan fún sísun ẹbọ níwájú rẹ̀?
7 “Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní awọ̀ oju ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú isẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí Baba à mi Dáfídì pèsè.
8 “Fi igi òpépé ránṣẹ́ sí mi, pínì àti lígúmì àwọn igi láti Lébánónì, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ.
9 Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nitorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀.
10 Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin onígi tí ó ń gé rírẹ́ náà ni ẹgbẹ̀rún kórísì (1,000), àlìkámà ilẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) kórísì ti bálì; ẹgbẹ́rùn lọ́nà (20,000) ogún ìwẹ̀ ọtí wáìnì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ìwẹ̀ òróró Ólífì.”
11 Hírámù ọba Tírè fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Sólómónì:“Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti se ọ́ ní ọba wọn.”