1 Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Édómù wá láti gbé ogun tọ Jéhóṣáfátì wá.
2 Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jéhóṣáfátì, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Édómù, láti apákejì òkun. Ó ti wà ní Hásásónì Támárì náà” (èyí ni wí pé, Énígédì).
3 Ní ìdágìrì, Jéhóṣáfátì pinnú láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde ààwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Júdà.
4 Àwọn ènìyàn Júdà sì kó ara wọn jọpọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Júdà láti wá a.
5 Nígbà náà Jéhóṣáfátì dìde dúró níwájú àpèjọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun.
6 O sì wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run àwọn bàba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóṣo lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀ èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.