16 Ní ọla, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú ibi ṣíṣe wa, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú ihà Jérúẹ́lì.
17 Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní àyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Olúwa tí yóò fi fún yín, ìwọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojú kọ wọ́n ní ọ̀la, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”
18 Jóhóṣáfátì tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù wólẹ̀ níwájú láti sin Olúwa.
19 Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ọmọ Kóhátì àti àwọn kórì sì dìde dúró wọ́n sì sin Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá.
20 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù wọ́n jáde lọ sí ihà Tékòa. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ, Jéhóṣáfátì dìde dúró ó sì wí pé, “Ẹgbọ́ mi, Júdà àti ènìyàn Jérúsálẹ́mù! Ẹ ní ìgbàgbọ́ ninú Olúwa Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì borí, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀ ẹ̀yìn yóò sì ṣe rere.”
21 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jéhóṣáfátì yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí ìwájú ogun ńlá náà, wí pé:“Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa,nítorí àànú rẹ̀ dúró títí láéláé.”
22 Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, Olúwa rán ogun ẹ́yìn sí àwọn ọkùnrín Ámónì àti Móábù àti òkè Séírì tí ó ń gbógun ti Júdà, wọ́n sì kọlù wọ́n.