2 Kíróníkà 20:21-27 BMY

21 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jéhóṣáfátì yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí ìwájú ogun ńlá náà, wí pé:“Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa,nítorí àànú rẹ̀ dúró títí láéláé.”

22 Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, Olúwa rán ogun ẹ́yìn sí àwọn ọkùnrín Ámónì àti Móábù àti òkè Séírì tí ó ń gbógun ti Júdà, wọ́n sì kọlù wọ́n.

23 Àwọn ọkùnrin Ámónì àti Móábu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Séírì láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin làti òkè Séírì, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run.

24 Nígbà tí Àwọn èníyàn Júdà jáde sí ìhà ilé ìsọ́ ní ihà, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí àyè sá.

25 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóṣáfatì ati àwọn èniyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀.

26 Ní ọjọ́ kẹ̀rin, wọn kó ara jọpọ̀ ní àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún Olúwa. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì ìbùkún títí di òní.

27 Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jéhóṣáfátì, gbogbo àwọn ènìyan Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí Olúwa ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn.