3 Ní ìdágìrì, Jéhóṣáfátì pinnú láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde ààwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Júdà.
4 Àwọn ènìyàn Júdà sì kó ara wọn jọpọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Júdà láti wá a.
5 Nígbà náà Jéhóṣáfátì dìde dúró níwájú àpèjọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun.
6 O sì wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run àwọn bàba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóṣo lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀ èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.
7 Ìwọ Ọlọ́run wa, ṣé o kò lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwajú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí o sì fi fún àwọn ọmọ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ láéláé?
8 Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé,
9 ‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-àrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sunkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’