31 Báyìí ni Jéhóṣáfátì jọba lórí Júdà. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Júdà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ásúbà ọmọbìnrin Ṣílíhì.
32 Ó sì rin ọ̀nà baba rẹ̀ Ásà kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, ó si ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa.
33 Ní ibi gíga, pẹ̀lúpẹ̀lù, kò mu wọn kúrò, gbogbo àwọn ènìyàn náà kò sì fi ọkan wọn fún Ọlọ́run àwọn baba wọn.
34 Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóṣáfátì, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sí inú ìwé ìtàn ti Jéhù ọmọ Hánánì, tí a kọ sí inú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì.
35 Nígbà tí ó yá, Jehóṣáfátì ọba Júdà da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Áhásáyà, ọba Ísírẹ́lì, ẹni tí ó jẹ̀bi búburú ìwà.
36 Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan okọ̀ láti lọ sí Táríṣísì, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Ésíonì-Gébérì.
37 Élísérì ọmọ Dáfídì ti Máréṣà sọtẹ́lẹ̀ sí Jóhóṣáfátì, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Áhásáyà, Olúwa yóò pa ohun ti iwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà.