1 Nígbà náà Jéhóṣáfátì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dáfídì. Jéhórámù ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
2 Àwọn ará kùnrin Jéhóramù ọmọ Jéhóṣáfatì jẹ́ Áṣáríyà, Jèhíeli, Ṣekárià. Ásáríyàhù, Míkáélí àti Ṣefátíá. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jéhóṣafátì ọba Ìsírẹlì.
3 Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bun púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Júdà, Ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jéhóramù nítori òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin.
4 Nígbà tí Jéhórámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó pa gbogbo àwọn arákùrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìrin ọba Ìsirẹ́lì.
5 Jéhórámù jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjọ.
6 Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé Áhábù ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìrin Áhábù. Ó ṣe búburú lójú Olúwa.