1 Ní ọdún kéje, Jehóádà fi agbára rẹ̀ hàn. O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso, ọrọrún kan, Ásáríyà ọmọ Jérohámù, Íṣímáẹ́lì ọmọ Jehóhánániì Ásáríyà ọmọ Óbédì, Máséyà ọmọ Ádáyà àti Élíṣáfátì ọmọ Ṣkírì.
2 Wọ́n lọ sí gbogbo Júdà, wọ́n sì pe àwọn ará Léfì àti àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn ará Ísírẹ́lì láti gbogbo àwọn ìlú jọ. Nígbà tí wọ́n wá sí Jérúsálẹ́mù.
3 Gbogbo ìpéjọ dá májẹ̀mú pẹ̀lú ọba ní ilé Ọlọ́run.Jéhóiádà wí fún wọn pé, “Ọmọkùnrin ọba yóò jọba, bí Olúwa ti ṣèlérí nípa àwọn àtẹ̀lé Dáfídì.
4 Nísinsinyìí èyí ni ohun tí ó yẹ kí ó ṣe: Ìdámẹ́ta àlùfáà yín àti àwọn ará Léfì tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi ni kí ó bojútó àwọn ìlẹ̀kùn.
5 Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé Olúwa.
6 Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé Olúwa yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítori tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó ṣọ ohun tí Olúwa ti yàn fún wọn.