6 Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé Olúwa yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítori tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó ṣọ ohun tí Olúwa ti yàn fún wọn.
7 Àwọn ará Léfì gbọ́dọ̀ wà ní ìdúróṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.”
8 Àwọn ará Léfì àti gbogbo ọkùnrin Júdà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehóádà Àlùfáà ti palásẹ. Olukúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jéhóiádà àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀.
9 Nígbà náà, ó fún àwọn alákòóso ọrọrún ní ọkọ̀ àti ńlá àti kékeré apata, tí ó jẹ́ ti ọba Dáfídì tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run.
10 Ó mú gbogbo àwọn ọkùnrin wà ní ipò ìdúró pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, yí ọba ká ní ẹ̀bá pẹpẹ àti ilé Olúwa láti ìhà gúsù sí ìhà àríwa ilé Olúwa.
11 Jéhóiádà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; Wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!”
12 Nígbà tí Ataláyà gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa.