2 Kíróníkà 24:6-12 BMY

6 Nítorí náà ọba paálásẹ fún Jéhóiádà olorí àlùfáà ó sì wí fún-un pé, “Kí ni ó dé tí o kò, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará Léfì láti mú wá láti Júdà àti Jérúsálẹ́mù, owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Ísírẹ́lì fún àgọ́ ìjẹ́rìí?”

7 Nísinsinyí, àwọn ọmọkùnrin, obìnrin búburú ni Ataláyà ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Báálì.

8 Nípasẹ̀ ọba, a ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa.

9 A ṣe ìkéde ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti bèèrè lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ní ihà.

10 Gbogbo àwọn ènìyàn mú gbogbo ìdá owó ti wọn wá pẹ̀lú ìdùnnú, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún.

11 Nígbà kígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Léfì sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọna àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí àyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédéé, wọ́n sì kó iye owó ńlá.

12 Ọba àti Jéhóiádà fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó gbé iṣẹ́ náà jáde ti a bèrè fún ilé Olúwa. Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé Olúwa padà, àti àwọn òsìsẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé Olúwa ṣe.