15 Ìbínú Olúwa ru sí Ámásíà, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “kí ni ó dé tí ìwọ fi ń bèrè lọ́wọ́ àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn ti wọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?”
16 Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgbà ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?”Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tísí ìmọ̀ràn mi”
17 Lẹ́yìn tí Ámásíà ọba Júdà ti bèèrè lọ́wọ́ àwọn olùgbà á lámọ̀ràn, ó rán ìpèníjà yìí sí Jehóáṣì ọmọ Jehóáháṣì ọmọ Jéhù, ọba Ísírẹ́lì pé: “Wá bá mi lóju kojú.”
18 Ṣùgbọ́n Jéhóáṣì ọba Ísírẹ́lì fèsì padà sí Ámásíà ọba Júdà pé, “Òṣùṣù kan ní Lẹ́bánónì rán isẹ́ sí òpépé (igi) ní Lẹ́bánónì, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwo. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lébánónì wá, ó sì tẹ òṣùṣù náà lábẹ́ ẹsẹ̀.
19 Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù àti nísinsin yìí ìwọ ní ìrera àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí o fi n wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lu?”
20 Ámásíà, bí ó tì wù kí ó rí kò ní tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jéhóásì lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Édómù.
21 Bẹ́ẹ̀ ni Jóásì, ọba Ísírẹ́lì: òun àti Ámásíà ọba Júdà dojúkọ ara wọn ní Bẹti Ṣeméṣì ní Júdà.