1 Áhásì sì jẹ́ ẹni ogún ọdún (20) nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún (16). Gẹ́gẹ́ bí i Dáfídì bàbá rẹ̀ kò sì ṣe ohun rere ní ojú Olúwa.
2 Ó sì rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì ó sì ṣe ere dídá fún ìsìn Báálì
3 Ó sì sun ẹbọ ní àfonífojì Hínómù, ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì
4 Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọ̀n nì lóri òkè kékeré àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.
5 Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Síríà lọ́wọ́. Àwọn ará Síríà sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Dámásíkù.Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbékùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa.
6 Ní ọjọ́ kan Pékà, ọmọ Remalíà, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà àwọn ọmọ ogun ní Júdà nítorí Júdà ti kọ Olúwa Ọlọ́run bàbá wọn sílẹ̀.