15 Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lu orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbékùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòǹhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọ̀n tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ, wọ́n sì padà sí Samaríà.
16 Ní àkókò ìgbà náà, ọba Áhásì ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà fún ìrànlọ́wọ́.
17 Àwọn ará Édómù sì tún padà wá láti kọlu Júdà kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ.
18 Nígbà tí àwọn ará Fílístínì sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n nì àti síhà gúsù Júdà. Wọ́n sẹ́gun wọ́n sì gba Béti-ṣémésì, Áíjálónì àti Gédérótì, àti Sókò, Tímínà, a ri Gímísò, pẹ̀lú ìletò wọn.
19 Olúwa sì rẹ Júdà sílẹ̀ nítorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ó sọ Júdà di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì se ìrékọjá gidigidi sí Olúwa.
20 Tílgátì-Pílésárì ọba Ásíríà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́.
21 Áhásì mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Ásíríà: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.