6 Ní ọjọ́ kan Pékà, ọmọ Remalíà, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà àwọn ọmọ ogun ní Júdà nítorí Júdà ti kọ Olúwa Ọlọ́run bàbá wọn sílẹ̀.
7 Síkíiì àti Éfúráímù alágbára sì pa Máséíẹ̀ ọmọ ọba, Ásíríkámù ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elikánà igbákejì ọba.
8 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kó ní ìgbékùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (2,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Saáríà.
9 Ṣùgbọ́n wòlíì Olúwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ódédì wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Saáríà. Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí Olúwa, Ọlọ́run Baba yín bínú sí Júdà ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run.
10 Nísinsinyìí ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Júdà àti Jerúsálémù ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò há jẹ̀bi Olúwa Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin?
11 Nísinsinyìí ẹ gbọ́ tèmi! Ẹ rán àwọn ìgbékùn tí ẹ̀yin ti mú gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹwọ̀n padà nítorí ìbínú kíkan Olúwa ńbẹ lórí yín.”
12 Lẹ́yìn náà, díẹ̀ nínú àwọn olórí ní Éfùráímù Ásáríyà ọmọ Jehóhánánì, Béríkià ọmọ Méṣílemóti, Jehísikíà ọmọ Ṣaílúmù, àti Ámásà ọmọ Hádíà, dìde sí àwọn tí o ti ogun náà bọ̀.