7 Wọ́n sì tún ti ìlẹ̀kùn ìloro náà pẹ̀lú, wọ́n sì pa Fìtílà. Wọn kò sì sun tùràrí tàbí pèsè ẹbọ sísun si ibi mímọ́ si Ọlọ́run Ísirẹ́lì.
8 Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìyanu àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i.
9 Ìdí nìyí tí àwọn bàbá wa ṣe ṣubú nípa idà àti idí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa ti wọn kó wọ́n ní ìgbékùn.
10 Nísinsìn yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.
11 Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsìn yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.”
12 Nígbà náà àwọn ọmọ Léfì wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́:nínú àwọn ọmọ Kóhátì,Máhátì ọmọ Ámásà: àti jóẹ́lì ọmọ Ásáríyà;nínú àwọn ọmọ Mérárì,Kíṣì ọmọ Ábídì àti Ásáríyà ọmọ Jéháiéíèlì;nínú àwọn ọmọ Gésónì,Jóà, ọmọ símà àti Édẹ́nì ọmọ Jóà;
13 nínú àwọn ọmọ Élisáfánì,Ṣímírì àti Jégíèlì;nínú àwọn ọmọ Ásáfù,Sékáríà àti Mátaníyà;