1 Hésékíà sì ránsẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà, ó sì kọ ìwé sí Éfúráímù àti Mánásè, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
2 Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì.
3 Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jérúsálẹ́mù.
4 Ọ̀ràn náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn.
5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Ísírẹ́lì láti Beerí-sébà àní títí dé Dánì, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.
6 Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé:“Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísáákì, àti Ísírẹ́lì, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Ásíríà.