2 Kíróníkà 30:7-13 BMY

7 Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́sẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí.

8 Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má se ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyà sí mímọ́ títí láé: Kí ẹ sì sin Olúwa, Ọlọ́run yín kí ìmúná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín.

9 Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí Olúwa, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí Olúwa Ọlọ́run yín, oníyọ́nú àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”

10 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn onísẹ́ náà kọjá lati ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Éfúráímù àti Mánásè títí dé Sébúlúnì: Ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n.

11 Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Áṣérì àti Mánásè àti Sébúlúnì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jérúsálẹ́mù.

12 Ní Júdà pẹ̀lú, ọwọ́ Ọlọ́run wá láti fún wọn ní ọkàn kan láti pa òfin ọba mọ́ àti tí àwọn ìjòyè, nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní oṣù kejì.