6 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti Júdà ti gbe inú àwọn ìlú Júdà pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun Ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkítì.
7 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣiṣe èyí ní oṣù kẹ́ta, wọ́n sì parí ní oṣù kéje.
8 Nígbà tí Heṣekáyà àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkítì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.
9 Heṣekáyà bèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì nípa òkìtì;
10 Sádókù sì dáhùn pé “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì sẹ́kù lọ́pọ̀lọpọ̀.”
11 Heṣekáyà pàsẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìpamọ́ nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí.
12 Nígbà náà wọ́n fi tọkàntọkàn mú ìdáwó wọn wá ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn yíyà sọ́tọ̀. Kónánáyà ará Léfì wà ní ìdí nǹkan wọ̀nyí àti arákùnrin rẹ̀ Ṣíméhì jẹ́ àtẹ̀lé e rẹ̀ lóyè.