16 Nígbà náà Ṣáfánì sì mú ìwé náà lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì ròyìn fún-un. “Àwọn ìjòyè rẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan tí a ti fi lé wọn lọ́wọ́.
17 Wọ́n ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa wọ́n sì ti fi lé àwọn alábojútó lọ́wọ́ àti àwọn òṣìsẹ́.”
18 Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sì sọ fún ọba, “Hílíkíyà àlùfáà ti fún mi ní ìwé.” Ṣáfánì sì kà níwájú ọba.
19 Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.
20 Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hílíkíyà, Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáíà ìránṣẹ́ ọ̀nà.
21 “Ẹ lọ kí ẹ lọ bérè lọ́wọ́ Olúwa fún mi fún àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti Júdà nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tíì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”
22 Híkíánì àti àwọn ènìyàn tí a yàn sì lọ láti sọ̀rọ̀ sí àwọn wòlíì Húlídà aya Ṣálúmù ọmọ Tókátì, ọmọ Hásíràh, olùtọ́jú ibi ìkásọsí, ó sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ní ìhà kejì.