18 Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sì sọ fún ọba, “Hílíkíyà àlùfáà ti fún mi ní ìwé.” Ṣáfánì sì kà níwájú ọba.
19 Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.
20 Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hílíkíyà, Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáíà ìránṣẹ́ ọ̀nà.
21 “Ẹ lọ kí ẹ lọ bérè lọ́wọ́ Olúwa fún mi fún àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti Júdà nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tíì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”
22 Híkíánì àti àwọn ènìyàn tí a yàn sì lọ láti sọ̀rọ̀ sí àwọn wòlíì Húlídà aya Ṣálúmù ọmọ Tókátì, ọmọ Hásíràh, olùtọ́jú ibi ìkásọsí, ó sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ní ìhà kejì.
23 Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé,
24 ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Júdà.