14 Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Árónì, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àsálẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Árónì àlùfáà.
15 Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Ásáfù, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dáfídì, Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì àwọn aríran ọba àti àwọn olùsọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ti múra sílẹ̀ fún wọn.
16 Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Jósíà ti paá lásẹ.
17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje.
18 Àjọ ìrékọjá náà kòsì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Ísírẹ́lì títí dé ọjọ́ wòlíì Sámúẹ́lì, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jósíà ti se, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo àwọn Júdà àti Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù.
19 Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejìdínlogún ìjọba Jósíà
20 Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Jósíà ti tún ilẹ̀ náà se tán, Nékò ọba Éjíbítì gòkè lọ láti bá Keríkemísì jà lórí odo Éúfírátè, Jósíà sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.