2 Kíróníkà 35:16-22 BMY

16 Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Jósíà ti paá lásẹ.

17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje.

18 Àjọ ìrékọjá náà kòsì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Ísírẹ́lì títí dé ọjọ́ wòlíì Sámúẹ́lì, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jósíà ti se, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo àwọn Júdà àti Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù.

19 Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejìdínlogún ìjọba Jósíà

20 Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Jósíà ti tún ilẹ̀ náà se tán, Nékò ọba Éjíbítì gòkè lọ láti bá Keríkemísì jà lórí odo Éúfírátè, Jósíà sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.

21 Ṣùgbọ́n Nékò rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, “Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrin èmi àti ìwọ, ọba Júdà? Kìí se ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà. Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bàá pa ọ́ run.”

22 Jósíà, bí ó ti wù kí ó rí, ẹni tí kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le báa jà, kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó lọ láti jà lórí àfonífojì Mégídò.