2 Kíróníkà 5:1-7 BMY

1 Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ti ṣe fún tẹ́ḿpìlì ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí Dáfìdì baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀: wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀sọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìsúra ilé Ọlọ́run.

2 Nígbà náà ni Sólómónì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ sí Jérúsálẹ́mù, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Májẹ̀mu Olúwa gòkè wá láti síónì ìlú Dáfídì.

3 Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́.

4 Gbogbo àwọn àgbààgbà Isirẹ́lì sì wá, àwọn ọmọ Léfì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa.

5 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ni ó mú wọn gòkè wá;

6 Nígbà náà ni ọba Sólómónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò leè kà tán rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò leè mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó.

7 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀ri ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.