2 Kíróníkà 6:10-16 BMY

10 “Olúwa sì ti mú ìléri rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dáfídì baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

11 Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti Olúwa bá àwọn Ísirẹ́lì ènìyàn mi dá wà.”

12 Nígbà naà ni Sólómónì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, ní iwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Isírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ méjèèjì.

13 Sólómónì ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárin àgbàlá ti òde. Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Isírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run.

14 Ó wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ ní ọ̀run àti ní ayé: ìwọ tí o pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi tọkàntọkàn wọn rìn ní ọ̀nà rẹ.

15 Ìwọ tí o pa ìlérí tí o ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi mọ́; nítorí ìwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí àti pé ìwọ ti fi ọwọ́ rẹ mú un ṣẹ; bí ó ti rí lónìí yìí.

16 “Nísinsinyìí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pa ìlérí tí ó ti ṣe mọ́ fún ìransẹ́ rẹ Dáfídì baba mi nígbà tí o wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ kù láti ní ọkùnrin láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Isírẹ́lì, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n bá kíyèsíara nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí òfin mi gẹ́gẹ́ bí o sì ti ṣe.’