10 Ní ọjọ́ kẹtàlélógún (23rd day) tí oṣù kéje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dáfídì àti Sólómónì, àti fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.
11 Nígbà tí Sólómónì ti parí ilé Olúwa àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé Olúwa àti nínú ilé òun tìkálárarẹ̀,
12 Olúwa sì farahàn ní òru ó sì wí pé:“Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibííyí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ.
13 “Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma báà sí òjò, tàbí láti pàsẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-àrùn sí àárin àwọn ènìyàn mi,
14 Tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn.
15 Nísisinyí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbíyìí.
16 Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.