1 Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ọmọ Ámónì sì kú, Hánúnì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
2 Dáfídì sì wí pé, “Èmi yóò ṣe ooré fún Hánúnì ọmọ Náhásì gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dáfídì sì ìránṣẹ́ láti tù ú nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀.Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ámónì.
3 Àwọn olórí àwọn ọmọ Ámónì sì wí fún Hánúnì Olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dáfídì rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.”
4 Hánúnì sì mú àwọn ìránṣẹ Dáfídì ó fá apákan irungbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúró ní agbádá wọn, títí ó fí dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.
5 Wọ́n sì sọ fún Dáfídì, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jẹ́ríkò títí irungbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”