2 Sámúẹ́lì 4 BMY

Ikú Íṣíbóṣétì.

1 Nígbà tí ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ pé, Ábínérì kú ní Hébírónì, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Ísírẹ́lì sì rẹ̀wẹ̀sì.

2 Ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Báánà, àti orúkọ ìkẹjì ní Rákábù, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì (nítorí pé a sì ka Béérótì pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì).

3 Àwọn ará Béérótì sì ti sá lọ sí Gítaímù, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí.

4 (Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìhìn dé ní ti Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì láti Jésírẹẹlì wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sá lọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sá lọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Méfíbóṣétì.)

5 Àwọn ọmọ Rímímónì, ará Béérótì, Rákábù àti Báánà sì lọ wọ́n sì wá sí ilé Iṣíbóṣétì ní ọsán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́ kan-rí.

6 Sì wò ó, bí Olùsọ́ ẹnú ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárin ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú àlìkámà; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rékábù àti Báánà arákùnrin rẹ̀ sì sá lọ).

7 Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sá lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà.

8 Wọ́n sì gbé orí Íṣíbóṣétì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù ọ̀ta rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kíri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba Olúwa mi lónìí lára Ṣọ́ọ̀lù àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”

9 Dáfídì sì dá Rákábù àti Báánà arakùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú.

10 Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, ‘Wò ó, Ṣọ́ọ̀lù ti kú,’ lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìhìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Síkílágì, ẹni tí ó ṣebí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìhìn rere rẹ̀.

11 Mélòó mélòó ni, nígbà tí àwọn ìká ènìyàn pa olódodo ènìyàn kan ni ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀—ǹjẹ́ èmi ha sì lè ṣe aláìbéèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín bí? Kí èmi sì mú yín kúrò láàyè.”

12 Dáfídì sì fi àṣẹ fún àwọn ọdọ́mọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì pa wọ́n, wọ́n sì gé ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn, a sì fi wọ́n há lórí igi ní Hébírónì. Ṣùgbọ́n wọ́n mú orí Íṣíbóṣétì, wọ́n sì sin ín ní ibojì Ábínérì ní Hébírónì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24