2 Sámúẹ́lì 2 BMY

A Yan Dáfídì Ní Ọba Júdà

1 Lẹ́yìn àkókò yìí, Dáfídì wádìí lọ́wọ́ Olúwa. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Júdà?” Olúwa sì wí pé, “Gòkè lọ.”Dáfídì sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?” Olúwa sì dáa lóhùn pé, “Sí Hébúrónì.”

2 Nígbà náà ni Dáfídì gòkè lọ ṣíbẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ méjì Áhínóámù ará Jésérẹ́lì, àti Ábígáílì obìnrin opó Nábálì ti Kámẹ́lì.

3 Dáfídì sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hébúrónì àti ìlú rẹ̀ mìíràn.

4 Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Júdà wá sí Hébúrónì, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi àmì òróró yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Júdà.Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì pé, àwọn ọkùnrin ti Jábésì Gílíádì ni ó sin òkú Ṣọ́ọ̀lù,

5 Ó rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jábésì Gílíádì láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Ṣọ́ọ̀lù ọ̀gá yín nípa sí sin ín.

6 Kí Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí.

7 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Ṣọ́ọ̀lù ọba yín ti kú, ilé Júdà sì ti fi àmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn.”

Ogun Láàárin Ilé Dáfídì àti Ṣọ́ọ̀lù

8 Lákòókò yìí, Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ṣọ́ọ̀lù ti mú Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù, ó sì mú un kọjá sí Máhánáímù.

9 Ó sì fi jẹ ọba lórí Gílíádì Áṣúrì àti Jésérẹ́lì àti lórí Éfúráímù àti lórí Bẹ́ńjámínì àti lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

10 Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba fún ọdún méjì. Ilé Júdà sì ń tọ Dáfídì lẹ́yìn.

11 Gbogbo àkókò tí Dáfídì fi jọba ní Hébúrónì lórí ilé Júdà sì jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.

12 Ábínérì ọmọ Nérì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Íṣíbóṣetì ọmọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù kúrò ní Máhánáímù, wọ́n sì lọ sí Gíbíónì.

13 Jóábù ọmọ Sérúíà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dáfídì jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gíbíónì. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún.

14 Nígbà náà, Ábínérì sọ fún Jóábù pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.”Jóábù sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é,”

15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dìde sókè, a sì kà wọ́n sí ọkùnrin méjìlá fún Bẹ́ńjámínì àti Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù àti méjìlá fún Dáfídì.

16 Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gíbíónì ti à ń pè ni Helikatihu Hasurímù.

17 Ogun náà ní ọjọ́ náà gbóná. Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì ṣẹ́gun Ábínérì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì.

18 Àwọn ọmọkùnrin Serúíà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó wà níbẹ̀: Jóábù, Ábíṣáì àti Ásáhélì. Nísinsìnyìí ẹṣẹ̀ Ásáhélì sì fẹ́rẹ̀ bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín tí ó wà ní pápá.

19 Ó ń lé Ábínérì, kò sì yípadà sí ọ̀tún tàbí sí òsì bí ó ti ń lé e.

20 Ábínérì bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, Ó sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ Ásáhélì ni?”Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,”

21 Nígbà náà, Ábínérì sọ fún un pé, “Yípadà sí ọ̀tún tàbí òsì; mú ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kí o sì bọ́ ìhámọ́ra rẹ.” Ṣùgbọ́n Ásáhélì kọ̀ láti dẹ́kun lílépa rẹ̀.

22 Ábínérì tún kìlọ̀ fún Ásáhélì, “Dẹ́kun lílépa mi! Èéṣe tí èmi yóò fi lù ọ́ bolẹ̀? Báwo ni èmi yóò ti wo arákùnrin rẹ Jóábù lójú?”

23 Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Ábínérì sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀: òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ́, ó sì kú ní ibi kan náà; ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Ásáhélì gbé ṣúbú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́.

24 Jóábù àti Ábíṣáì sì lépa Ábínérì: òòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Ámímà tí o wà níwájú Gíà lọ́nà ijù Gíbíónì.

25 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Ábínérì, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan.

26 Ábínérì sì pe Jóábù, ó sì bi í léèrè pé, “Idà yóò máa parún títí láéláé bí? Ǹjẹ́ ìwọ kòì tí ì mọ̀ pé yóò korò nikẹyìn? Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn.”

27 Jóábù sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn.”

28 Jóábù sì fọ́n ipè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Ísírẹ́lì mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́.

29 Ábínérì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bítírónì, wọ́n sì wá sí Mahanáímù.

30 Jóábù sì dẹ́kún àti máa tọ Ábínérì lẹ́yìn: ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kándínlógún ni ó kú pẹ̀lú Áṣáhélì nínú àwọn ìránṣẹ Dáfídì.

31 Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ Dáfídì sì pá nínú àwọn ènìyàn Bẹ́ńjámínì: nínú àwọn ọmọkùnrin Ábínérì; òjìdínní-rinwó ènìyàn.

32 Wọ́n si gbé Ásáhélì wọ́n sì sinín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Jóábù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hébírónì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24