2 Sámúẹ́lì 21 BMY

Àwọn Ará Gíbíónì Gba Ẹ̀san.

1 Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dáfídì ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí pé, Nítorí ti Ṣọ́ọ̀lù ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gíbíónì.

2 Ọba sì pe àwọn ará Gíbíónì, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gíbíónì kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Ámórì; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti búra fún wọn: Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà.

3 Dáfídì sì bi àwọn ará Gíbíónì léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kìn ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní Olúwa?”

4 Àwọn ará Gíbíónì sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrin wa àti Ṣọ́ọ̀lù tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Ísírẹ́lì.”Dáfídì sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?”

5 Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì.

6 Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gíbéà ti Ṣọ́ọ̀lù ẹni tí Olúwa ti yàn.”Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.”

Sísọ Àwon Ènìyàn Ṣọ́ọ̀lù Méje Rọ̀.

7 Ṣùgbọ́n Ọba dá Méfíbóṣétì sí, ọmọ Jónátanì, ọmọ Ṣọ́ọ̀lù, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrin Dáfídì àti Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù.

8 Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà bí fún Ṣọ́ọ̀lù, àní Ámónì àti Méfíbóṣétì àwọn ọmọkùnrin máràrùn ti Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, àwọn tí ó bí fún Ádíríélì ọmọ Básílíà ará Méhólátì.

9 Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gíbéà lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà-báálì.

10 Rísípà ọmọbìnrin Áíyà sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sán-an, tàbí àwọn ẹranko ìgbẹ́ lóru.

11 A sì ro èyí, tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà obìnrin Ṣọ́ọ̀lù ṣe, fún Dáfídì.

12 Dáfídì sì lọ ó sì kó egungun Ṣọ́ọ̀lù, àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jábéṣì-Gíléádì, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Bẹti-Sánì, níbi tí àwọn Fílístínì gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Fílístínì pa Sọ́ọ̀lù ní Gílíbóà.

13 Ó sì mú egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ.

14 Wọ́n sì sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jònátánì ọmọ rẹ̀ ní ilé Bẹ́ńjámínì, ní Sélà, nínú ibojì Kíṣì baba rẹ̀: wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ: lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà.

Ìṣẹ́gun Lórí Fílístínì.

15 Ogun sì tún wà láàrin àwọn Fílístínì àti Ísírẹ́lì; Dáfídì sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Fílístínì jà: ó sì rẹ Dáfídì.

16 Iṣibi-bénóbù sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òmìrán, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀dúnrún ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dáfídì.

17 Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Sérúíà ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Fílístínì náà, ó sì paá, Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí iwọ má ṣe pa iná Ísírẹ́lì.”

18 Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrin àwọn Ísírẹ́lì àti àwọn Fílístínì ní Góbù: nígbà náà ni Síbékáì ará Húṣà pa Sáfù, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn òmìrán.

19 Ìjà kan sì tún wà ní Góbù láàrin àwọn Ísírẹ́lì àti àwọn Fílístínì, Élíhánánì ọmọ Jáírì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sì pa arákùnrin Gòláyátì, ará Gátì, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdúbú igi tí a fi ń hun aṣọ.

20 Ìjà kan sì tún wà ní Gátì, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹṣẹ̀ mẹ́fà ní ẹṣẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní òmìrán.

21 Nígbà tí òun sì pe Ísírẹ́lì ní ìjà. Jónátanì ọmọ Ṣíméhì arákùnrin Dáfídì sì pa á.

22 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni a bí ní òmìrán ní Gátì, wọ́n sì ti ọwọ́ Dáfídì ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24