2 Sámúẹ́lì 5 BMY

A fi Dáfídì Jọba Lórí Gbogbo Ísírẹ́lì.

1 Gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí pé, “Wò ó, egungun rẹ àti ẹran ara rẹ ni àwa ń ṣe.

2 Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù fi jọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Ísírẹ́lì jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé: Olúwa sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ ó ṣe olùsọ́ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi, ìwọ ó sì jẹ́ olórí fún Ísírẹ́lì.’ ”

3 Gbogbo àgbà Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá ní Hébírónì, Dáfídì ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hébírónì, níwájú Olúwa: wọ́n sì fi òróró yan Dáfídì ní ọba Ísírẹ́lì.

4 Dáfídì sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba; ó sì jọba ní ogójì ọdún.

5 Ó jọba ní Hébírónì ní ọdún méje àti oṣù mẹ́fà lórí Júdà: ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà.

Dáfídì Fi Agbára Gba Jérúsálẹ́mù.

6 Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ àwọn ará Jébúsì, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; àwọn tí ó sì ti wí fún Dáfídì pé, “Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ́ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá” wọ́n sì wí pé, “Dáfídì kì yóò lè wá síhìn ín.”

7 Ṣùgbọ́n Dáfídì fi agbára gba ìlú odì Síónì: èyí náà ni í ṣe ìlú Dáfídì.

8 Dáfídì sọ lọ́jọ́ náà pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọlu àwọn ará Jébúsì, jẹ́ kí ó gba ojú àgbàrá, kí o sí kọlu àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú tí ọkàn Dáfídì kórìíra.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí pé, “Afọ́jú àti arọ wà níbẹ̀, kì yóò lè wọlé.”

9 Dáfídì sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dáfídì. Dáfídì mọ ìgànná yí i ká láti Mílò wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀.

10 Dáfídì sì ń pọ̀ si i, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

11 Hírámù ọba Tírè sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, àti igi kédárì, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dáfídì.

12 Dáfídì sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jọba lórí Ísírẹ́lì, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.

13 Dáfídì sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jérúsálẹ́mù wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hébírónì bọ̀: wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dáfídì.

14 Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jérúsálẹ́mù; Ṣamímúà àti Sóbábù, àti Nátanì, àti Sólómónì.

15 Àti Íbéhárì, àti Élíṣúà, àti Néfégì, àti Jáfíà.

16 Àti Élíṣámà, àti Élíádà, àti Élífélétì.

Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Fílístínì.

17 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dáfídì jọba lórí Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn Fílístínì sì gòkè wá láti wá Dáfídì; Dáfídì sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódì.

18 Àwọn Fílístínì sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Réfáímù.

19 Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Fílístínì bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí fún Dáfídì pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Fílístínì lé ọ lọ́wọ́.”

20 Dáfídì sì dé Baal-Perasímù, Dáfídì sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọta mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baal-Perasímù.

21 Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn.

22 Àwọn Fílístínì sì tún gòkè wá, wọ́n sì tan ara wọn kalẹ̀ ní àfonífojì Rafaímù.

23 Dáfídì sì bèèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òun sì wí pé, “Má ṣe gòkè lọ; ṣùgbọ́n bù wọ́n lẹ́yìn, kí o sì kọlù wọ́n níwájú àwọn igi Bákà.

24 Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá gbọ́ ìró ẹṣẹ̀ lórí àwọn igi Bákà náà, nígbà náà ni ìwọ yóò sì yára, nítorí pé nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ níwájú rẹ láti kọlù ogun àwọn Fílístínì.”

25 Dáfídì sì ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un; ó sì kọlu àwọn Fílístínì láti Gébà títí dé Gásérì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24