2 Sámúẹ́lì 7 BMY

Dáfídì Fẹ́ Láti Kọ́ Tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run

1 Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíká kiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.

2 Ọba sì wí fún Nátánì wòlíì pé, “Sá wò ó: èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kédárì kọ́, ṣùgbọ́n àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.”

3 Nátanì sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run Kọ̀ Fún Dáfídì Láti Kọ́ Tẹ́ḿpìlì.

4 Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Nátánì wá pé:

5 “Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dáfídì, pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé.

6 Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè ti ilẹ̀ Éjíbítì wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi.

7 Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Ísírẹ́lì, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kédárì kọ́ ilé fún mi.” ’

8 “Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dáfídì pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì.

9 Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sáà gé gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé.

10 Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó ti wọn, wọn kì yóò sì ṣípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójú mọ́, bí ìgbà àtijọ́.

11 Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.“ ‘Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ:

12 Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ijọba rẹ kalẹ̀.

13 Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé.

14 Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn.

15 Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ.

16 A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé: a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ”

17 Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí, bẹ́ẹ̀ ni Nátanì sì sọ fún Dáfídì.

Àdúrà Dáfídì

18 Dáfídì ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé:“Olúwa Ọlọ́run, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí?

19 Nǹkan kékeré ni èyí sáà jásí lójú rẹ, Olúwa Ọlọ́run; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí há ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Ọlọ́run?

20 “Àti kín ní ó tún kù tí Dáfídì ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Ọlọ́run mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ.

21 Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀.

22 “Ìwọ sì tóbi, Olúwa Ọlọ́run: kò sì sí ẹni tí ó dà bí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́.

23 Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dà bí àwọn ènìyàn rẹ, àní Ísírẹ́lì, àwọn tí Ọlọ́run lọ ràpadà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Éjíbítì wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn.

24 Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Ísírẹ́lì kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé; ìwọ Olúwa sì wá di Ọlọ́run fún wọn.

25 “Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí.

26 Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Ísírẹ́lì!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ.

27 “Nítorí pé ìwọ, Olúwa àwọn ọmọ-ogún, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ.’ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ.

28 Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì jásí òtítọ́, ìwọ sì jẹ́ jèẹ́ nǹkan rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ.

29 Ǹjẹ́, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bùkún ìdílé ìránṣẹ rẹ, kí ó wà títí láé níwájú rẹ: nítorí ìwọ, Olúwa Ọlọ́run, ni ó ti sọ ọ́: sì jẹ́ kí ìbùkún wà ní ìdílé ìránṣẹ́ rẹ títí láé, nípaṣẹ̀ ìbùkún rẹ.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24